This blog is all about happenings around the world of politics, sports, health, money, travel, stories and many more that matter
Thursday, 24 November 2016
alo apagbe(fables)
Ni igba laelae, ijapa ati igbin je ore korikosun. Gege bi a ti se mo... ijapa tiroko oko yannibo je ologbon ewe. Eredi ibadoreepo re pelu igbin ni lati le maa ri je lara re. Arijenimodaru eda ni oko yannibo. Ijapa gba igbin ore re ni imoran pe ki awon di jo maa se ode papo ninu igbo, igbin si gba imoran re wole. Igbin damoran pe ki awon maa de ebiti pa eran , ki awon mejeeji si jo maa ji wa woo ni kutu ai ni oroowuro. Ijapa si gba bee.
Won de ebiti nla kan sinu igbo, won si se adehun laarin ara won pe eran ti ebiti naa ba mu loojo, enikan ni yoo gbe e lo sile, eran ti o ba si tun mu nijo keji yoo je ti enikeji. Bi ile ti mo ni ojo keji, won ti ji de idi ebiti. Nigbati won woo, won rii pe o ti mu eku. Igbin mu eku naa, sugbon ijapa taku pe oun ni o ni eto lati koko mu eran ti ebiti pa. Igbin ko binu, o fun ijapa ni eku naa, o si so, fun un pe ki o maa mu un lo, nigba ti ebiti ba pa okete ni ola, oun yoo gbee. Ijapa roo titi, o rii pe, okete tobi ju eku lo, o si gba fun igbin lati maa mu eku naa lo, nigba ti o ba di ola, oun yoo gbe okete. Igbin si lo se eku je nile ni tire.
Nje ebiti tile gbe eran miiran bi?
Se eyin si ranti itan alo apagbe yii?
E dakun e bawa pari re.
Leyin naa ki e so awon eko ti a ri fayo ninu itan naa. E seun.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment
Please leave your comments here. Thanks.